Isikiẹli 22:28-31 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan.

29. Àwọn eniyan ilẹ̀ náà ń fi ipá gba nǹkan-oní-nǹkan; wọ́n ń ni talaka ati aláìní lára, wọ́n sì ń fi ipá gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn àlejò láì ṣe àtúnṣe.

30. Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.

31. Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Isikiẹli 22