Isikiẹli 21:19-32 BIBELI MIMỌ (BM)

19. “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú.

20. La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká.

21. Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran.

22. Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í.

23. Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ.

24. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25. “Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó.

26. Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀.

27. Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́.

28. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí:‘A ti fa idà yọ, láti paniyan.A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná.

29. Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn.

30. “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́.

31. N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun.

32. O óo di nǹkan ìdáná, lórí ilẹ̀ yín ni a óo pa yín sí, ẹ óo sì di ẹni ìgbàgbé, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Isikiẹli 21