8. Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.
9. Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.
10. Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbàtí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.
11. Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbárani a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.
12. Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,a sì jù ú sílẹ̀.Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.