Isikiẹli 19:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli,

2. kí n sọ pé:Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

3. Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;ó di ọ̀dọ́ kinniun.Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ.

4. Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti.

5. Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun.

6. Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,ó sì ń pa eniyan jẹ.

7. Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;ó sọ ìlú wọn di ahoro.Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀.

8. Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.

Isikiẹli 19