23. OLUWA Ọlọrun ní, “Lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ ibi wọnyi, o gbé! O gbé!
24. O mọ ilé gíga fún ara rẹ ní gbogbo gbàgede, o tẹ́ ìtẹ́ gíga fún ara rẹ ní ìta gbangba.
25. O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ.
26. O tún ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu àwọn ará Ijipti, àwọn aládùúgbò rẹ, oníṣekúṣe. Ò ń mú kí ìwà àgbèrè rẹ pọ̀ sí i láti mú mi bínú.
27. “Ọwọ́ mi wá tẹ̀ ọ́, mo mú ọ kúrò ninu ẹ̀tọ́ rẹ. Mo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ fi ìwọ̀ra gba ohun ìní rẹ, àwọn ará Filistini tí ìwà burúkú rẹ ń tì lójú.
28. “O bá àwọn ará Asiria ṣe àgbèrè ẹ̀sìn pẹlu, nítorí pé o kò ní ìtẹ́lọ́rùn sibẹ, lẹ́yìn gbogbo àgbèrè tí o ṣe pẹlu wọn, o kò ní ìtẹ́lọ́rùn.