11. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora.
12. Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ.
13. Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà.
14. Àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń já lọ sókè sódò bí ìgbà tí manamana bá ń kọ.
15. Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àgbá kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan.
16. Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn.
17. Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ.
18. (Àgbá mẹrẹẹrin ní irin tẹẹrẹtẹẹrẹ tí ó so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀). Wọ́n ga, wọ́n ba eniyan lẹ́rù. Àwọn àgbá mẹrẹẹrin ní ojú yíká wọn.
19. Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ti ń lọ ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a máa yí tẹ̀lé wọn, bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá gbéra nílẹ̀ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì gbéra nílẹ̀ pẹlu.
20. Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni àwọn ẹ̀dá náà máa ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì máa yí lọ pẹlu wọn, nítorí pé ninu àwọn àgbá náà ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà.
21. Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà.