10. Wọ́n wá ń kígbe pé, “Ti Ọlọrun wa tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan ni ìgbàlà.”
11. Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun.
12. Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!”
13. Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí bi mí pé, “Ta ni àwọn wọnyi tí a wọ̀ ní aṣọ funfun? Níbo ni wọ́n sì ti wá?”
14. Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.”Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.
15. Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé.
16. Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.