Ìfihàn 11:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”

4. Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú.

6. Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́.

7. Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n.

8. Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti.

Ìfihàn 11