Ìṣe Àwọn Aposteli 9:27-36 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku.

28. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa,

29. ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á.

30. Nígbà tí àwọn onigbagbọ mọ̀, wọ́n sìn ín lọ sí Kesaria, wọ́n fi ranṣẹ sí Tasu.

31. Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

32. Bí Peteru tí ń lọ káàkiri láti ibìkan dé ibi keji, ó dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun tí wọn ń gbé ìlú Lida.

33. Ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iniasi tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún mẹjọ; kò lè dá ara gbé nílẹ̀.

34. Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde.

35. Gbogbo àwọn tí ó ń gbé Lida ati Ṣaroni rí i, wọ́n bá yipada, wọ́n di onigbagbọ.

36. Ọmọ-ẹ̀yìn kan wà ní Jọpa, tí ó jẹ́ obinrin, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tabita, tabi Dọkasi ní èdè Giriki. (Ìtumọ̀ rẹ̀ ni èkùlù.) Obinrin yìí jẹ́ ẹnìkan tíí máa ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, ó sì láàánú pupọ.

Ìṣe Àwọn Aposteli 9