23. Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”
24. Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”
25. Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ.
26. Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.)
27. Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu,
28. ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya.