1. Lẹ́yìn ọjọ́ marun-un, Anania olórí Alufaa dé pẹlu àwọn àgbààgbà ati agbẹjọ́rò kan tí ń jẹ́ Tatulu. Wọ́n ro ẹjọ́ Paulu fún gomina.
2. Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní:“Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa.
3. Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín.