12. “Lẹ́yìn náà ni ọkunrin kan tí ń jẹ́ Anania dé. Ó jẹ́ olùfọkànsìn nípa ti Òfin Mose; gbogbo àwọn ẹni tí ń gbé Judia ni wọ́n sì jẹ́rìí rere nípa rẹ̀.
13. Ó dúró tì mí, ó ní, ‘Saulu arakunrin, lajú!’ Lẹsẹkẹsẹ ojú mi là, mo bá gbójú sókè wò ó.
14. Ó bá sọ fún mi pé, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó yàn mí tẹ́lẹ̀ pé kí n mọ ìfẹ́ rẹ̀, kí n fojú rí iranṣẹ Olódodo rẹ̀, kí n sì gbọ́ ohùn òun pàápàá;
15. kí n lè ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ níwájú gbogbo eniyan nípa ohun tí mo rí, ati ohun tí mo gbọ́.
16. Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.
17. “Nígbà tí mo ti pada sí Jerusalẹmu, bí mo ti ń gbadura ninu Tẹmpili, mo rí ìran kan.
18. Mo rí Oluwa tí ó ń sọ fún mi pé, ‘Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kíákíá, nítorí wọn kò ní gba ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa mi.’
19. Mo dáhùn, mo ní, ‘Oluwa, àwọn gan-an mọ̀ pé èmi ni mo máa ń sọ àwọn tí ó bá gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, tí mo sì máa ń nà wọ́n káàkiri láti ilé ìpàdé kan dé ekeji.
20. Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí wọ́n pa Stefanu, ẹlẹ́rìí rẹ, bí mo ti dúró nìyí, tí mò ń kan sáárá sí àwọn tí ó pa á tí mò ń ṣọ́ aṣọ wọn.’
21. Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ”