4. Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia.
5. Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi.
6. Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀.
7. Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru.
8. Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí.
9. Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú.