9. Ati ará Patia, ati ará Media ati ará Elamu; àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ Mesopotamia, ilẹ̀ Judia ati ilẹ̀ Kapadokia; ilẹ̀ Pọntu, ilẹ̀ Esia,
10. ilẹ̀ Firigia ati ilẹ̀ Pamfilia; ilẹ̀ Ijipti ati agbègbè Libia lẹ́bàá Kirene; àwọn àlejò láti ìlú Romu,
11. àwọn Juu ati àwọn aláwọ̀ṣe ẹ̀sìn Juu; àwọn ará Kirete ati àwọn ará Arabia, gbogbo wa ni a gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn iṣẹ́ ńlá Ọlọrun ní oríṣìíríṣìí èdè wa.”
12. Ìdààmú bá gbogbo àwọn eniyan, ó pá wọn láyà. Wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ èyí?”
13. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ní, “Wọ́n ti mu ọtí yó ni!”
14. Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.
15. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni.
16. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé,
17. ‘Ọlọrun sọ pé,“Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn,n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan.Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran,àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá.