20. Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.
21. Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀.
22. Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!”
23. Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa.
24. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri.
25. Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́.