1. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro.
2. Ṣugbọn wọn kò rò ó pé mò ń ranti gbogbo ìwà burúkú àwọn. Ìwà burúkú wọn yí wọn ká, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà níwájú mi.”
3. OLUWA wí pé, “Àwọn eniyan ń dá ọba ninu dùn, nípa ìwà ibi wọn, wọ́n ń mú àwọn ìjòyè lóríyá nípa ìwà ẹ̀tàn wọn.
4. Alágbèrè ni gbogbo wọn; wọ́n dàbí iná ààrò burẹdi tí ó gbóná, tí ẹni tí ń ṣe burẹdi kò koná mọ́, láti ìgbà tí ó ti po ìyẹ̀fun títí tí ìyẹ̀fun náà fi wú.
5. Ní ọjọ́ tí ọba ń ṣe àjọyọ̀, àwọn ìjòyè mu ọtí àmupara, títí tí ara wọn fi gbóná; ọba pàápàá darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́yà.
6. Iná ọ̀tẹ̀ wọn ń jò bí iná ojú ààrò, inú wọn ń ru, ó ń jó bí iná ní gbogbo òru; ní òwúrọ̀, ó ń jó lálá bí ahọ́n iná.
7. “Gbogbo wọn gbóná bí ààrò, wọ́n pa àwọn olórí wọn, gbogbo ọba wọn ni wọ́n ti pa léraléra, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó ké pè mí.”
8. OLUWA ní, “Efuraimu darapọ̀ mọ́ àwọn eniyan tí wọ́n yí wọn ká, Efuraimu dàbí àkàrà tí kò jinná dénú.
9. Àwọn àjèjì ti gba agbára rẹ̀, sibẹsibẹ kò mọ̀; orí rẹ̀ kún fún ewú, sibẹsibẹ kò mọ̀.
10. Ìgbéraga àwọn ọmọ Israẹli ń takò wọ́n, sibẹsibẹ wọn kò pada sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn, tabi kí wọ́n tilẹ̀ wá a nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe.
11. Efuraimu dàbí ẹyẹ àdàbà, ó jẹ́ òmùgọ̀ ati aláìlóye, ó ń pe Ijipti fún ìrànlọ́wọ́, o ń sá tọ Asiria lọ.
12. Ṣugbọn bí wọn tí ń lọ, n óo da àwọ̀n lé wọn lórí, n óo mú wọn bí ẹyẹ ojú ọ̀run; n óo sì jẹ wọ́n níyà fún ìwà burúkú wọn.
13. “Wọ́n gbé, nítorí pé wọ́n ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun yóo kọlù wọ́n, nítorí pé wọ́n ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Ǹ bá rà wọ́n pada, ṣugbọn wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.