1. Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i.
2. Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn.
3. Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?”
4. Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko.