Ẹsira 8:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àkọsílẹ̀ àwọn eniyan ati àwọn baálé baálé tí wọ́n bá mi pada wá láti Babiloni ní àkókò Atasasesi, ọba, nìyí:

2. Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Dafidi,

3. Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

4. Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

5. Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí;orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

6. Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí;orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

7. Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí;orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

Ẹsira 8