60. Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).
61. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀).
62. Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.
63. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA.
64. Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360).
65. Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin.
66. Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245)
67. Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720).
68. Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀.