Ẹkún Jeremaya 1:18-22 BIBELI MIMỌ (BM)

18. “Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe,nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀;ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan,ẹ kíyèsí ìjìyà mi;wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin milọ sí ìgbèkùn.

19. “Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi,ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí;àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú,níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri,tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára

20. “Bojúwò mí, OLUWA,nítorí mo wà ninu ìpọ́njú,ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́,nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ.Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ;bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.

21. “Gbọ́ bí mo ti ń kérora,kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu.Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi;inú wọn sì dùn,pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi.Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé,kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.

22. “Ranti gbogbo ìwà ibi wọn,kí o sì jẹ wọ́n níyà;bí o ti jẹ mí níyà,nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Ẹkún Jeremaya 1