1. Mose, pẹlu gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́.
2. Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.
3. Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín.
4. Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.
5. Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá.
6. Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀.
7. Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.
8. Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.”
9. Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín.
10. Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.”
11. Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní,
12. “Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre.