4. Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́.
5. Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un.
6. “Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀,
7. ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA.
8. Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.
9. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù.
10. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó;
11. tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀.
12. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín.