10. Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti.
11. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo sì bà wọ́n, ẹnikẹ́ni kò sì ní hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín.
12. “Bí ẹ bá gbọ́, ní ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti máa gbé, pé,
13. àwọn eniyan lásán kan láàrin yín ń tan àwọn ará ìlú náà jẹ, wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ bọ oriṣa.’
14. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín,
15. idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
16. Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́.