19. Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí.
20. Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.
21. Òun ni kí ẹ máa yìn, òun ni Ọlọrun yín, tí ó ṣe nǹkan ńláńlá tí ó bani lẹ́rù wọnyi fun yín, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.