23. Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí.
24. Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.”
25. Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á.
26. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.”
27. Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀.