Àwọn Ọba Keji 24:18-20 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó wà lórí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina.

19. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jehoiakimu baba rẹ̀.

20. Nítorí náà, OLUWA bínú sí Jerusalẹmu ati Juda; ó sì lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.

Àwọn Ọba Keji 24