Àwọn Ọba Keji 16:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe.

18. Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA.

19. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

20. Ahasi kú, wọn sì sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Hesekaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 16