20. Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.
21. Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
22. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
23. Nígbà tí ó di aadọta ọdún tí Asaraya jọba ní Juda, ni Pekahaya, ọmọ Menahemu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.
24. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA; ó sì tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.
25. Peka, ọmọ Remalaya, olórí ogun rẹ̀, pẹlu aadọta ọmọ ogun Gileadi dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní Samaria, ninu ilé tí a mọ odi tí ó lágbára yíká, tí ó wà ninu ààfin rẹ̀, Peka sì jọba dípò rẹ̀.
26. Gbogbo nǹkan yòókù tí Pekahaya ṣe, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
27. Ní ọdún kejilelaadọta tí Asaraya jọba ní Juda, ni Peka, ọmọ Remalaya, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ogún ọdún.
28. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.