23. Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”
24. Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́.
25. Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un,àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọbani ó fi gbé e fún un mu.
26. Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;ó fọ́ ọ lórí,ó lù ú ní ẹ̀bá etí,ó sì fọ́ yángá-yángá.
27. Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí.