19. Sisera bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ òùngbẹ ń gbẹ mí, fún mi lómi mu.” Jaeli bá ṣí ìdérí ìgò tí wọ́n fi awọ ṣe, tí wọ́n da wàrà sí, ó fún un ní wàrà mu, ó sì tún da aṣọ bò ó.
20. Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ”
21. Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú.
22. Bí Baraki ti ń wá Sisera kiri, Jaeli lọ pàdé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, n óo sì fi ẹni tí ò ń wá hàn ọ́.” Baraki bá bá a wọlé lọ, ó sì bá Sisera nílẹ̀ níbi tí ó kú sí, pẹlu èèkàn àgọ́ tí wọn gbá mọ́ ọn lẹ́bàá etí.
23. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọrun bá àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Jabini, ọba àwọn ará Kenaani.