1. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi.N óo gbé ọ ga:n óo yin orúkọ rẹ.Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu,o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́,o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.
2. O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpào sì ti pa àwọn ìlú olódi run.O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́.
3. Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ.