Aisaya 15:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí:Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo,ó parí fún Moabu.

2. Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún.Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba.Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.

3. Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba.Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn,ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún,omijé sì ń dà lójú wọn.

Aisaya 15