15. OLUWA yóo pa Ijipti run patapata.Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.
16. Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.