Òwe 25:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni àwọn òwé mìíràn tí Sólómónì pa, tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà ọba Júdà dà kọ.

2. Ògo Olúwa ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

3. Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jìnbẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

4. Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákàohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà

5. mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọbaa ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípaṣẹ̀ òdodo.

6. Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì

7. Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn ín”ju wí pé kí ó dójú tì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

8. Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rímá ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìnbí aládùúgbò rẹ bá dójú tì ọ́?

9. Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,má ṣe tú àsírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

10. àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójú tì ọ́orúkọ burúkú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

11. Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹó dàbí èṣo wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

Òwe 25