1. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè jéró Sámúsónì mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láàyè láti wọlé.
2. Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣebí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jù lọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”
3. Sámúsónì dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Fílístínì ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.”
4. Òun sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjìméjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀.
5. Ó fi iná ran àwọn ètúfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Fílístínì. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn oko àjàrà àti ólífì.
6. Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀.