Jónà 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ngbà náà ni Jónà gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,

2. Ó sì wí pé:“Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa,òun sì gbọ́ ohùn mi.Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún iraǹwọ́,ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.

3. Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú,ní àárin òkun,ìṣàn omi sì yí mi káàkiri;gbogbo bíbì omi àti rírú omiré kọjá lórí mi.

4. Nígbà náà ni mo wí pé,‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ;ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ èmi yóò túnmáa wo ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.’

5. Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;ibú yí mi káàkiri,a fi koríko odò wé mi lórí.

6. Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá;ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí:ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi.

Jónà 2