4. Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”
5. Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbààgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró tí tí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dáríúsì kí wọ́n sì gba èsì tí à kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6. Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tétanáì, olórí agbégbé Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbégbé Yúfúrátè, fi ránṣẹ́ sí ọba Dáríúsì.
7. Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:Sí ọba Dáríúsì:Àlàáfíà fún un yín.
8. Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.
9. A bi àwọn àgbààgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”
10. A sì tún bèèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn silẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.
11. Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹ́ḿpìlì ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.
12. Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinésárì ti Kálídéà, ọba Bábílónì lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Bábílónì.