Rom 7:6-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ṣugbọn nisisiyi a fi wa silẹ kuro ninu ofin, nitori a ti kú si eyiti a ti dè wa sinu rẹ̀: ki awa ki o le mã sìn li ọtun Ẹmí, ki o má ṣe ni ode ara ti atijọ.

7. Njẹ awa o ha ti wi? ofin ha iṣe ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. Ṣugbọn emi kò ti mọ̀ ẹ̀ṣẹ, bikoṣepe nipa ofin: emi kò sá ti mọ̀ ojukokoro, bikoṣe bi ofin ti wipe, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro.

8. Ẹ̀ṣẹ si ti ipa ofin ri aye, o ṣiṣẹ onirũru ifẹkufẹ ninu mi. Nitori laisi ofin, ẹ̀ṣẹ kú.

9. Emi si ti wà lãye laisi ofin nigbakan rì: ṣugbọn nigbati ofin de, ẹ̀ṣẹ sọji, emi si kú.

10. Ofin ti a ṣe fun ìye, eyi li emi si wa ri pe o jẹ fun ikú.

11. Nitori ẹ̀ṣẹ ti ipa ofin ri aye, o tàn mi jẹ, o si ti ipa rẹ̀ lù mi pa.

12. Bẹ̃ni mimọ́ li ofin, mimọ́ si li aṣẹ, ati ododo, ati didara.

13. Njẹ ohun ti o dara ha di ikú fun mi bi? Ki a má ri. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ ki o le farahan bi ẹ̀ṣẹ o nti ipa ohun ti o dara ṣiṣẹ́ ikú ninu mi, ki ẹ̀ṣẹ le ti ipa ofin di buburu rekọja.

14. Nitori awa mọ̀ pe ohun ẹmí li ofin: ṣugbọn ẹni ti ara li emi, ti a ti tà sabẹ ofin.

15. Nitori ohun ti emi nṣe, emi kò mọ̀: nitori ki iṣe ohun ti mo fẹ li emi nṣe; ṣugbọn ohun ti mo korira, li emi nṣe.

16. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ eyini li emi nṣe, mo gba pe ofin dara.

Rom 7