9. Ipọnju ati irora, lori olukuluku ọkàn enia ti nhuwa ibi, ti Ju ṣaju, ati ti Hellene pẹlu;
10. Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu:
11. Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun.
12. Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ;
13. Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare.
14. Nitori nigbati awọn Keferi, ti kò li ofin, ba ṣe ohun ti o wà ninu ofin nipa ẹda, awọn wọnyi ti kò li ofin, jẹ ofin fun ara wọn:
15. Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn,
16. Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.
17. Ṣugbọn bi a ba npè iwọ ni Ju, ti o si simi le ofin, ti o si nṣogo ninu Ọlọrun,
18. Ti o si mọ̀ ifẹ rẹ̀, ti o si dán ohun ti o yàtọ wò, ẹniti a ti kọ li ofin;