O. Daf 136 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ọpẹ́

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

3. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

4. Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

5. Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

6. Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

7. Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

8. Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

9. Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

10. Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

11. O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

12. Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

13. Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

14. O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

15. Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

16. Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

17. Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

18. O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

19. Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

20. Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

21. O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

22. Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

23. Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

24. O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

25. Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;

26. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.