O. Daf 122 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìyìn Jerusalẹmu

1. INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa.

2. Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu.

3. Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan.

4. Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa.

5. Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi.

6. Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere.

7. Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ.

8. Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ!

9. Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ.