O. Daf 105 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.

2. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo.

3. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.

4. Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.

5. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀;

6. Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀.

7. Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.

8. O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.

9. Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;

10. O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye.

11. Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.

12. Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀.

13. Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran;

14. On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn;

15. Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi,

16. Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ.

17. O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú:

18. Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin:

19. Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò.

20. Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

21. O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀.

22. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n.

23. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu.

24. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ.

25. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.

26. O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn.

27. Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu.

28. O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀.

29. O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn.

30. Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn.

31. O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn.

32. O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn.

33. O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn.

34. O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye.

35. Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run.

36. O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn.

37. O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀.

38. Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn.

39. O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru.

40. Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun.

41. O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ.

42. Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀.

43. O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀:

44. O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na.

45. Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.