Num 31:27-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ki o si pín ikogun na si ipa meji; lãrin awọn ologun, ti o jade lọ si ogun na, ati lãrin gbogbo ijọ.

28. Ki o si gbà ohun idá ti OLUWA lọwọ awọn ologun ti nwọn jade lọ si ogun na: ọkan ninu ẹdẹgbẹta, ninu awọn enia, ati ninu malu, ati ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran:

29. Gbà a ninu àbọ ti wọn, ki o si fi i fun Eleasari alufa, fun ẹbọ igbesọsoke OLUWA.

30. Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA.

31. Ati Mose ati Eleasari alufa si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

32. Ati ikogun ti o kù ninu ohun-iní ti awọn ologun kó, o jẹ́ ọkẹ mẹrinlelọgbọ̀n o din ẹgbẹdọgbọ̀n agutan,

33. Ẹgba mẹrindilogoji malu,

34. Ọkẹ mẹta o le ẹgbẹrun kẹtẹkẹtẹ,

35. Ati enia ninu awọn obinrin ti kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dàpọ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun.

36. Ati àbọ ti iṣe ipín ti awọn ti o jade lọ si ogun, o jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan ni iye:

37. Idá ti OLUWA ninu agutan wọnni jẹ́ ẹdẹgbẹrin o din mẹdọgbọ̀n.

38. Ati malu jẹ́ ẹgba mejidilogun; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ mejilelãdọrin.

39. Kẹtẹkẹtẹ si jẹ́ ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgọta o le ọkan.

40. Awọn enia si jẹ́ ẹgba mẹjọ; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgbọ̀n o le meji.

41. Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

42. Ati ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, ti Mose pín kuro ninu ti awọn ọkunrin ti o jagun na,

43. (Njẹ àbọ ti ijọ jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan,

44. Ati ẹgba mejidilogun malu.

Num 31