Num 3:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa.

4. Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.

5. OLUWA si sọ fun Mose pe,

6. Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.

7. Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.

8. Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.

9. Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.

10. Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a.

11. OLUWA si sọ fun Mose pe,

12. Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe:

13. Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.

14. OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai pe,

Num 3