38. Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu.
39. Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu.
40. Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani.
41. Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ.
42. Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn.