Mat 12:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ.

2. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi.

3. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀:

4. Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa?

5. Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi?

6. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin.

7. Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi.

8. Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi.

Mat 12