Mak 7:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe.

9. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́.

10. Mose sá wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ; ati Ẹnikẹni ti o ba sọrọ baba tabi iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀ na:

11. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bi enia ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, Korbani ni, eyini ni Ẹbùn, o bọ́.

12. Bẹ̃li ẹnyin ko si jẹ ki o ṣe ohunkohun fun baba tabi iya rẹ̀ mọ́;

13. Ẹnyin nfi ofin atọwọdọwọ ti nyin, ti ẹ fi le ilẹ, sọ ọ̀rọ Ọlọrun di asan; ati ọpọ iru nkan bẹ̃ li ẹnyin nṣe.

14. Nigbati o si pè gbogbo awọn enia sọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ fi etí si mi olukuluku nyin, ẹ si kiyesi i:

15. Kò si ohunkokun lati ode enia, ti o wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ti o le sọ ọ di alaimọ́: ṣugbọn nkan wọnni ti o ti inu rẹ̀ jade, awọn wọnni ni isọ enia di alaimọ́.

16. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

17. Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na.

18. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye tobẹ̃? ẹnyin ko kuku kiyesi pe, ohunkohun ti o wọ̀ inu enia lati ode lọ, ko le sọni di alaimọ́;

19. Nitoriti ko lọ sinu ọkàn rẹ̀, ṣugbọn sinu ara, a si yà a jade, a si gbá gbogbo onjẹ danù?

Mak 7