36. Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ.
37. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ?
38. O si wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? ẹ lọ wò o. Nigbati nwọn si mọ̀, nwọn wipe, Marun, pẹlu ẹja meji.
39. O si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o mu gbogbo wọn joko li ẹgbẹgbẹ lori koriko.
40. Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta.
41. Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn.
42. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó.
43. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.
44. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.
45. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.
46. Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.
47. Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ.