Mak 3:6-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.

7. Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin,

8. Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.

9. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.

10. Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn.

11. Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun.

12. O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn.

13. O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá.

14. O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu,

15. Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade:

16. Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru;

17. Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá:

18. Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,

19. Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.

20. Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ.

21. Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ.

22. Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.

23. O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade?

Mak 3