30. Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u.
31. O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn.
32. Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá.
33. Gbogbo ilu si pejọ li ẹnu-ọ̀na.
34. O si wò ọ̀pọ awọn ti o ni onirũru àrun sàn, o si lé ọ̀pọ ẹmi èṣu jade; ko si jẹ ki awọn ẹmi èṣu na ki o fọhun, nitoriti nwọn mọ̀ ọ.
35. O si dide li owurọ̀ ki ilẹ to mọ́, o si jade lọ si ibi iju kan, nibẹ li o si ngbadura.
36. Simoni ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si nwá a.
37. Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ.
38. O si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miran, ki emi ki o le wasu nibẹ̀ pẹlu: nitori eyi li emi sá ṣe wá.
39. O si nwãsu ninu sinagogu wọn lọ ni gbogbo Galili, o si nlé awọn ẹmi èṣu jade.
40. Ọkunrin kan ti o dẹtẹ si tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ niwaju rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́.
41. Jesu ṣãnu rẹ̀, o nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o si wi fun u pe, Mo fẹ, iwọ di mimọ́.
42. Bi o si ti sọ̀rọ, lojukanna ẹ̀tẹ na fi i silẹ; o si di mimọ́.